Languages
Content Who? About us Events Submissions Submenu
« back

Mo ti ri

Jùmọké Bọlanle Adéyanju (2016)

Mo ti ri

Ilé mi daru
ọtá mi ti sa lo
ọmọde nbo
ko si nkankan mo.

sugbon, ẹ bami ko s’ilẹ
wipe: mo ti ri!

Gbogbo jati jati laye yi
pẹlu jaye jaye ti won wi

Emi nikan mo ti ri

ẹjẹ l’oju mi
omi lati f’oju mi, o ti ton
ẹjẹ l’oju mi

ile mi daru
awon ọrẹ mi won ti sa lo
ọmọde nbo
ko si nkankan mo.

oju nti mi – nibo ni aiye mi lo?
jowo, maa fi mi s’ilẹ naa.

Mo ti ri.
Ifé ton koja bayi.
iku ton wa mi kakiri, wallahi
Mo ti ri.

E ko s’ilẹ.

Ile mi daru
ọkọ mi ti sa lo
ọmọde nbo
ko si nkankan mo

eye fe ri mi
labalaba oun k’orin olomi.

omi l’oju mi
ọwọ lati f’oju mi, mi o ni
omi l’oju mi
E ko s’ilẹ.
ọla wo ma gbere l’ati pe mi Iya Ejiayo
Otun ọla wo ma beere alafia oko mi

Ile mi daru
mi o ni sa lo
ọmọde nbo
mi o ni ke mo

Nitori mo ti ri ayọ mi
adùn
ogun
oshun
b’o sun
maa pada s’ile titilaye

 

– Yorùbá –

≡ Menu ≡
Homepage Content
Events Submissions
Authors Translators Moderators
About us Partners Gallery
Contact Blog Facebook
Festival 2016 Events Press